Smiley face

Yoruba Dun: Itan igbe aye Olabisi K 39

Yoruba Dun: Itan igbe aye Olabisi K 39
#ayeOlabisiK39


Sii Olootu,

Bi awọn eniyan ilu Yoruba Dun ko se jẹ ki Olootu gbadun, bẹẹ gẹlẹ ni Olootu n yọ emi naa lẹnu nipa itesiwaju lẹta mi.

Bi o tilẹ jẹ wi pe mo n ro lọkan bi ẹ ni wi pe ki n da lẹta naa duro, sugbon Olootu kojalẹ lati jẹ ki n figi gun-un.

Mo pada pade ẹgbọn ọrẹ mi ti o jẹ agbẹjọro (ọrẹ mi ti mo pade ni ile itura).

A ko gbogbo ẹjọ a ro fun agbẹjọro yii, pelu ẹ̀rí ohùn ọga mi ti a ka silẹ ninu fọnran. Sugbon ohun ibanujẹ lo jẹ fun mi nigba ti agbẹjọro sọ ohun ti ofin sọ fun mi.

O sọ wi pe won ki i gba ohùn lasan mọ ni ile ẹjọ gẹgẹ bi ẹri. O ni ile ejo gba wi pe, ogbon alumonkọrọyi le wa ninu ohun ti won ka sile gẹgẹ bi eri.

O ni amohunmaworan (fidio) nikan ni ẹri ti won le gba wọle ni ile ẹjọ. Okan mi bajẹ nitori wi pe eri kan soso ti mo ni niyi lati bọ ninu iya ayeraye ti ọga mi fẹ fi jẹ mi.

Agbẹjọro yii ni ki n ma ba ọkan jẹ, o ni ti ẹru ba kan oke to tun kanlẹ, o ni o tun nibi taa gbe e si. Mo dupe lọwọ rẹ. Ojo idajọ pe, a ko ri loya ko yoju.

Enu ofifo ki i dun yanmuyanmu.

Boya tori owo ti mi o ri ko fun un ni o jẹ kose bẹẹ. Sugbon oun naa lo se ileri wi pe oun yoo ran mi lowo. Sugbon adajo ko da ẹjọ ohun ni ọjọ naa, n se ni won sun ẹjọ naa siwaju niketi ti won gbe faali ẹjọ wa le adajo lọwọ.

Nigba ti mo pade de ile, ọgbọn kan ta si mi ninu. Mo ro wi pe o seese ki n bọ ninu ọran yii ti mo ba le ri iyawo oga mi yii ki n rojọ fun un pelu ẹri. O seese ko le ran mi lọwọ. Mo n ro, sugbon ọna ti mo fẹ gbe gba ko ti yemi.

Bi maa se rin pade iyawo oga mi yii gan mi o ti mo. Sugbon mo ro wi pe o ye ki n le ri ona abayo ti mo ba wakan. Nitori mi o lowo dani ti mo fe fi sejo, oga loya to seleri ni o mu ileri se yii bee si ni a ri ori oko afesona mi nita.

E maa binu, maa danu duro naa. Sugbon mo fi dayin loju pe mi o ni pe e pada de

Emi ni tiyin ni tooto,
Olabisi K
Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment