Smiley face

Odun kerin leyin ti irawo Bisi Komolafe jabo loju orun

Bisi Komolafe
Ti ba n ranti eni ti n be laye,  awon Yoruba ni ko buru taa ba tun seranti eni ti n be lajule orun. Sebi kosi eni ti ko ni ku laye, ki Edumare je ki ojo wa pe laye ninu alaafia.

Awon Yoruba a tun ma dasa wi pe, oju ni i kan mojesin ti n ku, sebi yoo pada rorun naa ni to ba dagbalagba.

Inu ibanuje nla ni awon osere ati agbo amuludun Naijiria fi paju odun 2012 de pelu bi Bisi Komolafe Veronica se jade laye lojo kokanlelogbon osu kejila odun 2012 (31-12-2012).

Odun 1986 ni won bi oserebirin naa, ojo kerin osu kinni odun 2013 ni won gbe wonu ile sun lo.

Orisiirisii awuyewuye lo romo iku osere naa, sugbon ko si ogbon ninu awijare ti adajo ti da tan. Edumare lo mo ohun ti eniyan ko mo.


Bisi, a fe o sugbon Oluwa fe o ju wa lo.  Ma sun laya Olugba re titi dojo ajinde. RIP 


Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment