Smiley face

Ali Modu Sheriff n mura ija, Ahmed Makarfi n leri, PDP n mi dugbedugbe lori omi

PDP Crisis: Ali Modu Sheriff vs. Ahmed Makarfi 
Siamaanu egbe PDP apapo, Ali Modu Sheriff, eni ti ile ejo kotemilorun da lare gege bi eni ti yoo ma tuko egbe alaburada lo ti leri bayii wi pe, enikeni ko gbodo pe Ahmed Makarfi ni adari apakan PDP mo. 


O ni PDP ko pe meji, okan soso ni. O ni eni to ba pe Ahmed Makarfi ni adari apakan PDP, ko ba je awon oniroyin, oun yoo gbe won lo si ile ejo ni. 

Sugbon sa, awon apa kan ti won je ti Ahmed Makarfi so wi pe, omo aijobe ri ni Ali Modu Seriff ati wi pe, awon si n lo sile ejo to gaju lati yanju oro naa.

Ti e ko ba gbagbe, laipe yii ni awon igun mejeeji sepade po lati yonju aawo to wa laaarin won. Sugbon o dabi eni wi pe, bi igba eniyan yin agbado seyin igba ni ipade won ti won se naa yori si.
Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment