Smiley face

Isele Tuntun: Kilonsele laaarin Olori Wuraola ati Ooni Enitan Ogunwusi Ile Ife?

Orisirisi awuyewuye lo ti n lo kaakiri nipa Olori Wuraola to je aya Ooni Enitan Ogunwusi ti ile Ife, eleyii to n so wi pe, omobirin naa ti ko oko re sile.

Bi o tile je wi pe ko si aridaju iroyin naa, bakan naa ni oro kankan ko ti i jade lati aafin Oonirinsa yala lati tako iroyin naa tabi jeri si i.

Olayemi Oniroyin gbiyanju lati pe Ogbeni Moses Olafera, amugbalegbe Ooni leka iroyin, lati mo bi oro naa seri. Sugbon gbogbo igbiyanju lati kan si okunrin naa lo jasi pabo pelu bi ko se gbe ero re.

Sugbon sa, ajodun odun ife kan waye lana,15-08-2017, niluu Ile Ife eleyii ti enikeni ko ri olori Wuraola legbe oba alaso funfun.

Aimoye awon eniyan lo jade pelu awon olosun naa ti won se ti won, gbogbo ilu n jo, tomode tagba si n yo.

Gege bi itopinpin Olayemi Oniroyin Agbaye, awon kan fi ye wa wi pe, Olori kan sare jade lo si ilu Eko lasan ni ati wi pe, aya baba ko ni pe pada wa sile.

Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment