Smiley face

Ìpínlẹ̀ Plateau gbé Buhari sókè lonii

Ààrẹ Muhammadu Buhari, ẹni tí wọn fún ni inagijẹ "Baba go slow" ní kété to gorí aleefa látàrí aitete yàn àwọn minisita rẹ, lo ti padà dá "go slow" sílè báyìí ni ìpínlẹ̀ Plateau lónìí (8/3/2018) nígbà tó ń ṣe abewo pàtàkì sì ipínlẹ̀ naa.

Gbogbo ìlú lo tú jáde bí ẹni wí pé wọn rí olùgbàlà aráyé. Wọn pariwo Sai Baba, nígbà tí àwọn kan an rankadeede rẹ.

Atokunrin atobirin ni wọn yọ mọ ọ bí ìgbà ọmọdé rẹyẹ.

Sáájú kìí ọkọ Aisha to de, láti owuro kùtùkùtù, ní wón ti ti gbogbo ojú popona pa pátápátá. Tí àwọn sójà kò gberegbe sì dúró loju àwọn òpópónà gbogbo.

Ṣùgbọ́n sá, àwọn ẹgbẹ́ alátakò, PDP, ni wọn fi owó ra àwọn ènìyàn náà ní kìí se wi pe ìfẹ́ Buhari lopọ tó bẹ́ẹ̀ lọ́kàn wọn.

@OlayemiOniroyin

Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment