Smiley face

Mo kò sọ́wọ́ Taju l'Ayẹyẹ n'Ibadan

Àwọn tí ènìyàn ń ro wí pé yóò nira fún láti wọ ìjọba ọrùn lè padà jẹ ẹni àkọ́kọ́ ti yóò wọlé.

Nígbà tí àwọn ènìyàn mímọ́, tí a lérò wí pé wọn jókòó níbí gíga nínú párádísè, lè padà je èròjà tí wọn fi dáná ọrùn àpáàdì.

Ẹ yé fojú ẹlẹṣẹ wo ẹnikẹ́ni, Ọlọ́run nìkan ló mọ ibi tẹda ó sùn níkẹyìn.

Àǹfààní ni ore ṣíṣe jẹ, ìbùkún sì ni. Ipokipo to bá wà má banujẹ, sì ma dúpẹ́ lọ́wọ́ Olúwa Ọba.

Òtítọ́ ni wí pé, to bá yá kosi ẹ̀dá kàn tí yóò kú níbi, gbogbo wa là má rekọja lọ. Àwọn ẹni àná dá?

Ayẹyẹ n'Ibadan ni mo wá lónìí pelu ọrẹ mi àtijọ́, Tajú. Odun kẹwàá ni yìí tí mo ti rí kẹyin. Taju to f'obirin méjì lóyún lẹẹkan náà 😂. Amala ni mo kọ́kọ́ jẹ́. Ní báyìí, ó tún ní kí wọn lọ bá mi ra èkuru wá. Mo kò sọwọ Taju poo!

Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment