Smiley face

Kò sí ìgbà táa dásọ tá rilẹ fiwọ́

Enikan ra motor lónìí , bóyá lẹ́yìn ọdún márùn-ún tàbí mẹ́wàá ni Èdùmàrè to gbọ́ àdúrà rẹ. Ìwọ náà ra, adùn ibẹ ni wí pé, motor àsìkò ni ti ẹ jẹ nígbà tí èyí tí ọrẹ rẹ ni ni nǹkan bi ọdún mẹ́wàá sẹ́yìn jẹ àtijó.

Kò ni ìtumò iye àwọn ènìyàn tó ti lọ ṣáájú rẹ, kété to bá ti mókè, gbogbo yín tí di ọkàn ṣoṣo - Alaseyori.

Gbogbo àwọn ọrẹ rẹ tí n bímọ ìwọ ó sì ti lóko. Nígbà tí ìgbà rẹ bá dé, tí ìwọ náà di ọlọmọ, abiyamọ ni wọn wọn má pé gbogbo yín. Kini ìtumò àlàyé mi? Itunmo rẹ ni wí pé, kosi ìgbà táa dásọ táa rilẹ fi wọ.

Àwọn ọrẹ rẹ tí ń fò lókè lọ sí ilu America, Canada, UK, ṣùgbọ́n kò ti kan ọ. Se suuru! Kosi ìgbà tó wọlé siluu Òyìnbó tí ó  ni rí tiẹ̀ ṣe.

Ma banujẹ, má pẹ̀gàn ẹnikẹ́ni, má ṣe rìkíṣí enibọọdi, ìdí ni wí pé, tí àkókò rẹ bá dé, ó má de pẹ̀lú ariwo àti òkìkí ńlá ni.

Olayemi Olatilewa ni orúkọ mi. Mo sì ti gbà káàdì #PVC mi sọ́wọ́.

Ẹ kú ikalẹ

Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment