Smiley face

Oludasilẹ Facebook, Mark Zuckerberg pé ẹni ọdún mẹ́rinlelọgbon (34) lónìí

Òní, 17/05/18, ni ọjọ́ ìbí oludasile Facebook, Mark Zuckerberg, eléyìí tí gbogbo wa njẹ àǹfààní rẹ lónìí.

Kí n tó  kí Mark fún ayẹyẹ ọjọ́ ìbí ọdún mẹ́rinlelọgbon (34) to pé lọnii.
Mo rọ yín kí ẹ fún ní àǹfààní láti sọ díẹ̀ nínú ohun tí mo kọ nípa ìgbésí ayé arákùnrin náà.

Ǹjẹ́ ẹ mọ wí pé ìṣòro ẹlòmíì bẹ̀rẹ̀ lọjọ to gba sabuke jáde nílé ìwé? Bẹẹni, ìwé ẹ̀rì ni kò jẹ ki ẹlòmíì tètè ròkè gùn kíákíá. Kò sí ohun tó burú nínú kí ènìyàn fi ìwé ẹ̀rí rẹ ṣiṣẹ́. Ṣùgbọ́n àwọn kan kọ̀ láti wá ọgbọ́n míì dá yàtò sì ohun tí ìwé ẹ̀rí wọn lé pèsè fún wọn.

Àìmọye àwọn ènìyàn ní wón jáde iléèwé lọ́dọọdún. Àwọn tí wọn rà foomu JAMB lọ́dọọdún láti wọ ilé ìwé kò níye. Àwọn ilé ìṣe tuntun ń sá fún orileede wá. Àwọn tó ti wà nílè  tẹ́lẹ̀ ń kógbá wọlé ní joojumọ. Ìwádìí fi hàn wí pé nǹkan yóò má burú sí i ni àyàfi tí àwọn ìjọba ṣe àwọn ètò to yẹ nípa ètò ọrọ̀-ajé, ààbò, àti igbayegbadun.

Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment