Smiley face

Abàmì ẹlẹ́dẹ̀ tí dífá fún Super Eagles nípa Russia 2018

Ẹlẹ́dẹ̀ abàmì tó  sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa wí pé, Donald J. Trump ìlú Amẹrika ni yóò jaye olubori gẹ́gẹ́ bí Ààrẹ ilẹ̀ Amẹ́ríkà tí kéde wí pé ikọ́ agbabọọlu Nàìjíríà, Super Eagles, yóò dé ipele tó kangun sì asekagba (Semi Final) nínú idije ìfẹ́ agbaye FIFA to ń lọ lọ́wọ́ ni Russia 🇷🇺.

Gẹ́gẹ́ bi ìtàn nípa ẹlẹ́dẹ̀ tí orúkọ rẹ ń jẹ Mystic Marcus, ẹni ọdún mẹ́jọ yìí ṣe fi hàn, ẹlẹ́dẹ̀ náà kò sọ àsọtẹ́lẹ̀ rí lai wá sí ìmúṣẹ pàápàá jù lọ nípa ere idáraya.

Lára àwọn orileede tí yóò kopa ninu ipele tó kangun sì asekagba gẹ́gẹ́ bí Mystic Marcus ṣe fi hàn ni Belgium, Uruguay ati Argentina.

Njẹ ẹyin nígbàgbọ́ nínú Ifá tí Mystic Marcus da báyìí?

Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment