Smiley face

Russia 2018: Pele àti Maradona tí wọlé

Ààrẹ ìlú Russia 🇷🇺, Putin, fún ra rẹ lo kí Pele kaabọ si orile-ede Russia fún igbaradi ìfẹ́ agbaye tí yóò wayé ni orile-ede náà.

Pele ọmọ ilu Brazil, ọkùnrin mẹta tí ìgbà ọkùnrin kò lè dá dúró lọ́nà lórí ọdan ti dẹni tí ń fi kẹkẹ rìn báyìí.

Pupọ àwọn ọmọdé agbaboolu tí wọn wo Pele gẹ́gẹ́ bí awokọse ni àkókò rẹ lórí pápá gan-an tí fehinti báyìí. Eléyìí sì ń ṣe àpẹẹrẹ Pele gẹ́gẹ́ bí Baba-baba tí a bá ń sọ nípa ère boolu alafesẹgba.

Ọrẹ rẹ to dimọ ninu foto yíi, Diego Maradona, ọmọ orileede Argentina 🇦🇷 náà jẹ igi ńlá láwùjọ ere bọọlu àgbáyé.

Ní àwọn ọdún 90s sẹ́yìn, arábìnrin Omodele Sarafa, tó jẹ́ ajábọ̀ ìròyìn ère Idaraya NTA ṣe àpèjúwe Maradona gẹ́gẹ́ bí iná ẹlẹntiriki tí kò ṣe gbamu ni akoko to wá lórí ọdan.

Fún akitiyan Maradona àti Pele, Àjọ FIFA fi àmì-ẹyẹ FIFA PLAYER OF THE CENTURY da awon mejeeji lọ́là lodun 2000.

Ọba mẹ́wàá ìgbà mẹ́wàá loni ilé ayé. Igba kan lọ, ìgbà kan bọ sì ni ọ̀rọ̀ ilé ayé jẹ.

Kanu lo fiya je Brazil àti Argentina ni Atlanta 96 ni orileede Amẹ́ríkà 🇺🇸 lẹ́yìn tí Pele àti Maradona tí jókòó sílè. Kò sí ìlú náà lagbaye tí wọn kò ti mo JJ Okocha gẹ́gẹ́ bí ọba idán. Kanu ò gbà bọọlu mọ, Okocha gan-an tí lọ sí mi sara, sugbon gbogbo wọn ní wá ni Russia báyìí láti wòran àwọn ògo tuntun taye ń sọ lọ́wọ́lọ́wọ́.

E jẹ ka lọ sí Russia ⚽ 🏃 🏃

Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment