*Ajimobo, Ambode, Aregbe
ati Amosun bu ola fun Oba Odulana
*Gbogbo oja ni won tipa
lojo ti won sin Olubadan
*“Alailabawon oba ile
Yoruba ni Odulana”- Buhari
*“Ojulowo omo Olubadan ni
emi naa”- Osinbajo
Gbogbo oja nlanla to wa
niluu Ibadan pata ni won tipa lojo Eti to koja yii (12/02/16) nigba ti won gbe
Oba Samuel Odulana Odugade wonu kaa ile lo. Eleyii ni won se lati fi bu ola fun
Olubadan to waja lojo kokandinlogun osu kinni odun yii (19/01/2016). Ninu eto
isinku eleyii to waye ni St. Peter’s Cathedra to kale si Aremo, Ibadan ni
orisiirisii otokulu ti gbe pejo lati seye ikeyin fun oba to gbese leni odun
mokanlelogorun (101).
Lara awon to wa nikale ni
gomina ipinle Oyo to tun je olugbalejo agba, Senato Abiola Ajimobi, Gomina
Ibikunle Amosun lati ipinle Ogun, Ogbeni Rauf Aregbesola lati ipinle Osun.
Bakan naa ni Ogbeni Akinwunmi Ambode lati ipinle Eko ko gbeyin nibi ayeye eto
isinku ojo naa.
Awon eniyan ti OLAYEMI
ONIROYIN tun kofiri nibi ayeye naa ni minisita fun eto ibanisoro, Ogbeni Bayo
Shittu. Gomina ipinle Osun nigba kan ri, Senato Isiaka Adeleke. Bakan naa ni
Oloye Harry Akande ati aya gomina ipinle Oyo nigba kan ri naa, Alhaja Mutiat
Ladoja, wa lati wa fi ijoko ye Oba Odulana to dologbee si.
Nibi ayeye eto isinku yii,
eleyii ti won ti bere lati ojo kefa osu
keji odun yii (06/02/16), ni igbakeji aare orileede Naijiria, Ojogbon Yemi Osinbajo
ti gbe soju Aare Muhammadu Buhari. Ninu oro Buhari, eleyii ti igbakeji n re
jise re, lo ti n se alaye Oba Odulana gege bi oba kan pataki ti ko labawon ni
ile kaaro-o-ji-i-re.
“Inu mi dun, mo si tun ri
bi anfaani nla lati wa nibi lonii. Ki i se nipa jije asoju fun Aare bi ko se
ojuse mi gege bi ojulowo omo Olubadan. A ni lati dupe lowo Oluwa oba mimo wi pe
iru eniyan takuatakun bi oba Odulana gba aarin wa koja,” Osinbajo se laye naa
bee.
Leyin eto isinku yii ni won
gbe oku Oba Odulana lo si Igbo Elerin nibi won ti gbe bi lomo lojo kerinla osu
kerin odun 1914 to wa ni ijoba ibile Lagelu. Ibi naa ni won ti feeru fun eeru,
ti won si fi erupe fun erupe leyin ti won gbe Oba Odulana wonu kaa ile lo.
0 comments:
Post a Comment