“Awa mo bi won se n
maneeji omo nipinle Osun” Aregbe
Nibayii, Gomina ipinle
Osun, Ogbeni Rauf Aregbesola ti fowo si abadofin eleyii ti yoo maa se afihan
awon owo ina ati eto ijoba nipa rira awon dukia ijoba ati akanse ise ti ijoba n
gbe jade. Abadofin to ti pada dofin nipa ibuwolu gomina ni won daba re lodun to
ko ja eleyii ti won pe akole re ni Public Procurement Law 2015. Ogbeni Aregbe
se alaye ofin tuntun yii gege bi ona lati mu idaniloju ijoba otito inu, ododo
ati gbangba lasa n ta gbile nipinle Osun.
"Eto ara ilu ni lati mo gbogbo bi owo ilu se n di lina, ohun ti won na le lori ati bi ijoba se na owo naa lekunrere. Awon nnkan bayii yoo se anfaani fun eto oro aje wa, paapa julo, awon olokoowo alabode," gomina se ninu alaye re bee.
Ninu alaye gomina nile
ijoba l’Ojoru ose to koja nibi to ti n buwo lu abadofin naa lo tun fi kun wi
pe, ojuse awon alase ni lati maa na owo ilu gege bi bo ti ye yato si ina apa to
kun owo awon oloselu aye ode oni.
Laipe yii ni iwe iroyin
kan se lalaye wi pe, papako ofurufu wa lo diwo ju ninu awon papako ti awon
ipinle kan ti won mule ti wa ko. Bi o tile je wi pe papako wa lo ni oju ona a ti
sare baalu to gun ju ti won lo, sibesibe, owo ti ipinle Osun na ko to ti won.
Bakan naa ni awon ileewe nla ti a n ko ni won so wi pe, owo ti a fi ko kere jojo
si ohun ti awon eniyan fojun sun lo,” Gomina tun fi kun alaye re bee.
Gomina ko tun sai menuba
anfaani ofin tuntun naa, eleyii ti yoo fi aye sile fun awon eniyan lati riran
wonu eto ijoba, eleyii ti yoo si mu ijoba lati ma se isiro owo ti won na fun
awon ara ilu to ran won nise.
0 comments:
Post a Comment