Awon ti won wa ise NIS |
*Ebi awon to ku nibi won
ti n wase NIS ti fe ja sayo
Ijoba apapo Naijiria labe
akoso Muhammadu Buhari ti setan lati pese ise fun ebi awon eniyan ti won padanu
emi won nibi won ti n wase labe eka ile ise ijoba ti n risi wole-wode, Nigerian
Immigration Service (NIS).
Aba lati fun ebi awon
eniyan yii nise ni ijoba to gbese labe akoso Goodluck Jonathan se ileri lati
pese ise fun ni ona ati tu won ninu latari bi won se padanu awon eniyan won.
Sugbon ti ijoba naa ko mu ileri re se titi won fi lo igba won tan lori aga
isakoso.
Sugbon ileri yii ni
minisita fun eto abenu, Abdulrahman Danbazau, tun gbedide pelu idaniloju wi pe
ijoba to wa lode yii yoo mu ileri naa se.
Danbazau lo so eleyii di mimo leyin to wa salaye awon eto owo isuna eka
ile isejoba to di mu fun ile igbimo asofin. Ninu oro re pelu awon oniroyin lo
ti n fi da won loju wi pe, gbogbo eto ni awon ti se lati tu idile naa ninu nipa
ipase ise leka ile ise ijoba. O ni eto die bayii lo ku ati ifikunlukun pelu
awon igbimo ijoba toro naa kan.
0 comments:
Post a Comment