Adeboye ati Ooni Ojaja |
Olori ijo irapada, Alufaa
E.O Adeboye, eni ti won bi si Ifewara lodun 1942, ti lo se abewo si aafin Ooni
Ojaja II, Oba Adeyeye Ogunwusi ti ilu Ile Ife ni Ojoru ose to koja yii.
Ninu abewo wooli Olorun alaaye si aafin Oba Ogunwisi, lo ti n gbe orinyin rabande fun oba to gba opa ase lojo keje osu kejila odun to koja yii (07/12/2015) fun awon ise takuntakun ti oba alaye naa gunle lati mu ki ife ati isokan pada sile Yoruba.

"Ti gbogbo ile Yoruba ba wa ni isokan, ohun to daju ni wi pe awon ogo igbaani ti a ti padanu yoo pada te wa lowo. Inu mi dun lati maa gbo nipa igbiyanju Ooni tuntun ati akitiyan re lati mu ile Yoruba wa ni isokan. Mo si gbadura wi pe, gbogbo ohun rere ti okan wa poungbe ni ile Yoruba ni yoo te wa lowo loruko Jesu", Baba Adeboye se adura bayii ninu alaye re.
Ninu esi Ooni Ogunwusi,
oba-a-ji-woso-funfun, dupe pupo lowo wooli naa latari adura re ti fi n ran ile
Yoruba lowo nigba gbogbo. O si ro awon ojise Olorun yoku lati ma wo awokose
Adeboye ki gbogbo nnkan le tete pada bo sipo laipe ojo.
0 comments:
Post a Comment