Smiley face

Awon Omo Elegbe Okunkun Parapo Lati Ja Fun Ilu Baba Won

Ni Ipinle Edo, awon omo elegbe okunkun ni awon ile iwe giga ipinle naa ti fi imo se okan bayii lati gbogun ti awon ajinigbe ati awon adigunjale ti won ti n yo alaafia ipinle naa lenu lati igbayi wa.

Bakan naa la gbo wi pe gomina ipinle naa, Gomina Adam Oshiomhole titi to fi dori awon oba alaye pata ni won pinnu lati se atileyin fun awon omo elegbe okunkun naa.

Sebi won ni ebi ko ti pa Hausa ni fi n pe eleko ni 'Mai kafa' ti owo ebi ba te, Mai Ilori' ni yoo maa pariwo.

Tayotayo ni ijoba ipinle Edo fi gba aba naa, bi o tile je wi pe ominu n ko awon ara ilu.

Lara awon egbe okunkun ti won pejo sibi ipada naa ni Green Circuit ti inagije re nje Maphites, Norsemen ti adape re tun je Vikings, Black Axe, Eiye confraternity ati bee bee lo.
Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment