Smiley face

Orin Caro Da Wahala Sile Ni Ilu Ghana: Awon Omoge Yabo Wizkid Lati 'Caro' Re loju Paali

Lojo Satide to koja yii Ayo Balogun o si nile, ilu Ghana lo ti lo te pepe faaji ni ode The Guinness Big Eruption Concert.

Ohun to jo ni loju ni bi awon omoge ilu Aganyin se ya wo oju agbo ni kete ti Wizkid gbenu le orin Caro ti won si ni dandan a fi ti awon ba di mo irawo omo olorin naa.

Awon omoge yii ni awon lawon n je Caro awon si setan lati fidan han Wizkid nita gbangba nibe naa, to ba to bee ko je ka won da sile ka won tun tun sa.

Bi awon omoge se n gbiyanju ki won 'caro' Wizkid bee ni omo naa n be sihin-sohun ti n korin lo laigbara duro rara.

Awon eruku ti won n daabo bo Wizkid le awon omobirin yii ti, won ni a fi ti awon ba dimo Wizkid ni tipatipa.

Opelope awon agbofinro, awon omo esubeleke yii da pati ariya ru die lo ku.
Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment