![]() |
Charla Nash |
Sebi owo ti ada mo naa lo n ka ada lehin. Awon Yoruba so wi pe iku omi ni i pa agbaoje omuwe lodo. Bi jagunjagun ba jagun titi, ti ko ba deyin leyin ogun afaimo ki ogun maa pada gbe won lo.
Sebi ore timotimo ni Charla Nash ati obo langido ti won ti jo n sere lati ojo to ti pe. Sugbon lojo kan, omo eranko pajuda si Charla Nash ni ojo ti inu bi i. Obo fo oju olowo re, o ba imu Charla je, gbogbo ehin enu re lo wu jade kuro ninu erigi, die loku omo inaki ko ba pa omo eniyan.
Leyin opolopo inira, awon dokita gbiyanju lati ba Charla Nash se agbelero oju tuntun , imu ati ehin re ko le maa ri nnkan je eja tutu. Sugbon gege bi oro awon Yoruba, oju apa ko le jo oju ara.
Inu osu keji odun 2009 gan ni isele yii sele nigba ti Charla pada wale lati wa se agbako ijamba ibi yii lowo obo to so di idakuda . Opelope awon olopa ti won gbebon fun omo eranka alagidi yii ki Charla to bo lowo iku ojiji. Odindin odun meji gbako lo gba awon onimo isegun ti Brigham and Women's Hospital to wa Boston lati da oju, imu ati ehin Charla pada.
Apejuwe awon dokita nipa ijamba Charla Nash Ati ogbon ti won fe da lati ba se eda oju tuntun ni Brigham and Women's Hospital.
Agbarijopo ogbologbo awon dokita onimo ijinle isegun ti won gbon bi Ifa ti Brigham and Women's Hospital .
Nibayii, Charla Nash ti se alaye ara re gege bi eni to n gbe ninu ibanuje okan nipa aibegbemu, ikosile lati odo awon eniyan re ati igbe aye ti ko si ominira lati se ohun gboggbo to fe lati okan re.
Bi o tile je wi pe awon olopa ti seku pa obo to se ise ibi naa, sugbon awon Yoruba so wi pe obe ge ni lowo a so obe nu, obe ku ti se ohun to fe se.
Aworan Charla Nash saaju ojo ibi.
Aworan Charla Nash leyin isele buruku to sele si.
0 comments:
Post a Comment