Smiley face

Iroyin Kayeefi: Apa Kan Ejo, Apa Kan Eniyan


Mai Li Fay

Gege bi iwe iroyin World News Daily Report se so, aimoye awon eniyan ni won ti n ya ketiketi lo wo omobirin Mai Li Fay omo ilu Bangkok, Thailand eni odun mejo ti apa kan re je eniyan, apa kan si je ejo.

Bi o tile je wi pe awon onimo isegun salaye ohun ti won mo nipa iru aisedeede ninu iru iseda bee, sibesibe kayeefi naa lo je fun gbogbo eniyan pata.

Bi iru nnkan bayii se n se apere ohun abami, ti ko si si obi (iya ati baba) kankan ti o gbadura ki ohun bi iru omo bayii lomo, ohun ni awon kan ri gege bi ipadabo orisa si ile aye eleyii ti won bo.

Ibanuje ati ayo ni eleyii je fun awon obi omo naa pelu bi gbogbo aye se n lo pe wo iran omo naa eleyii to si n di owo fun won.

Sebi Yoruba ku ti pari oro, won ni were dun-un wo loja ni, ko se e bi lomo.

Edumare ma je ki ohun ti o da yale gbogbo wa. Amin
 
Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment