Smiley face

Itan Ibanuje Abiamo Ni Ilu Amerika


Eledumare saanu fun awon abiyamo aye ti won sunkun, pese omo rere fun awon ti ko ri omo bi. Iroyin yii ba ni lokan je gidi gan-an, sugbon o di dandan ki n royin re faraye gege bi ohun oju mi ri. Mo si toro gafara pupo nipa si se afihan iru awon aworan bayii.
 
Alexis Fretz, to ti loyun omo re leyin bi ose bi mokandinlogun (19 weeks) ni eje sadeede n jade lara re. Omobirin yii kesi awon agbebi fun iranlowo, won si gbe digbadigba lo si ile iwosan Indiana. Ile iwosan naa lo ti pada bi omo yii laipe ojo, o si ba ni lokan je wi pe omo ti won so oruko re ni Walter Joshua Fretz pada ku leyin to wa saye tan ni ile iwosan.
 
Omobirin yii ya aworan oku omo yii pelu ebi re lati se afihan re fun gbogbo aye.
Igbagbo re ni wi pe boya sise afihan awon aworan naa le je ibere atunse gege bi ona abayo fun awon alaboyun ti won maa n padanu oyun won laipe ojo ni ilu Amerika.







 

Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

3 comments:

  1. Afi oluwa saanuu fun wa. A ko ri iru eleyyii ri, eru la fi n da bo oloro

    ReplyDelete