Smiley face

Ilu Ukraine Ti Daru

Rogbodiyan ti bẹ silẹ ni ilu Ukraine laaarin awon alatako ijọba ti won je ara ilu ati awon agbofinro. Awon eniyan bi meedogbon ni won ti ba isẹlẹ naa lọ bayii nigba ti awon eniyan bi ọọdunrun ti fara pa yannayanna ninu wahala naa.


Aare ilu Amerika lagbọ wi pe o ti ke si Aare ilu Ukraine, Ogbeni Viktor Yanukovych lati pẹtu si aáwọ̀ ti n sẹlẹ ni inu ilu naa. Aare ilẹ Amerika tun tẹnumo wi pe dandan ni fun awon olori ilu Ukraine  lati tẹti si ohun ti awon ara ilu n fẹ ni ona ti o le mu alaafia pada bọ si po.

Lara ohun ti n bi awon eniyan ilu Ukraine ninu ni iwa jegudujera to gbilẹ laaarin awon alase inu naa ati awon igbesẹ ijọba lai ro ti awon ara ilu ti won je mẹkunnu. Sugbon awon ijọba so wi pe awon oloselu alatako ni won n ko si awon eniyan ninu lati tako ijoba ni ọna ati gba ijọba. Ile ise iroyin CNN agbaye naa ko sai tẹ pẹpẹ alaye nipa rogbodiyaan naa. Ẹ tun le ka siwaju [NIBI]






















Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment