Smiley face

Iyawo Ti Pa Aburo Ọkọ Rẹ Sile


Ile ẹjọ Magistrate to wa ni Ebute Meta ti pasẹ ki won lọ ti arabirin Obiageri Oriuwa ẹni ọdun mọkandinlọgbọn pẹlu bi o se gun aburo ọkọ rẹ lọbe pa mọle.

Isẹlẹ buruku yii lo sele ni
opopona Ladega to wa ni Apapa Ajegunle ni Ipinle Eko.


Gẹgẹ bi a se gbọ, ọkọ Obiageri Oriuwa  gan-an ko gbe ni ilu yii, ẹyin odi ni ọkọ rẹ n gbe. Ile kan naa si ni oun ati aburo ọkọ rẹ n gbe papọ.


Saaju ọjọ ti Obiageri Oriuwa  gun aburo ọkọ rẹ lọbe pa yii, iwadii awon ọlọpa sọ wi pe Obiageri Oriuwa tan ẹ̀rọ amunawa jẹnẹratọ mójú eleyii to gbana jẹ lọganjọ oru to jẹ wi pe diẹ lo ku ki gbogbo ile jona.

Ọrọ yii gan-an lo fa gbanmi-si-omi-ò-to laaarin awon mejeeji latari ohun ti aburọ ọkọ rẹ korò ojú si gẹgẹ bi iwa aini akiyesi.

Oro naa ti de ile ẹjo bayii, esun ti won si ka si lẹsẹ ree ni ile ijọ:


 “That you, Obiageri Oriuwa, on January 28, 2014, about 8.30am, at 54, Ladega Street, Olodi Apapa Ajegunle, Lagos in the Lagos Magisterial District, did unlawfully kill one Ikechukwu Oriuwa, aged 37 years, by stabbing him with a kitchen knife and thereby committed an offence punishable under Section 221 of the Criminal Law of Lagos State, Nigeria 2011.”


Bi o tilẹ je wi pe onidajo Omidan Y.J Badejo-Okusanya ti sun igbẹjọ naa siwaju, awon agbẹjọro fun Obiageri Oriuwa,  agbejọro C.J Okoro ati Spurgeon Ataene ko sai sọ fun ile ẹjọ lati fi oju mii wo ọrọ naa yato si ẹsun apaniyan ti won fi kan Obiageri Oriuwa. Won ni nibi igbiyanju onibara awon lati daabo bo ara rẹ ni isẹlẹ naa ti sẹlẹ, ko ba si dara ki ile ẹjọ fi oju aanu wo.
Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment