Ojo kerin osu kejila odun 1982 je ojo
ibanuje nla ni Melbourne to wa ni orileede Austrialia, ojo ti ayo di ibanuje, ojo
ti ologbon sunkun, ti awon omugo n kigbe ti ko si seni to le so fun enikan wi
pe ko dake ekun ni sisun, ojo naa ni won bi Nick Vujicic gege bi eni ti ko lapa ti ko si lese.
‘I was born and raised in Melbourne, Australia, and it was shock to my parents that I arrived without limbs . There is no medical reason for it.’
Gege bi Olarewaju Adepoju se so lodun1972 ;
‘...eni ija o deba ni i pe ara re lokunrin, eni aye ba da yerepe adanwo si lagbada
to ba ri omo awo ko ni pegan’.
‘At age eight, I could not see a bright future ahead and I became depressed. When I was ten years old, I decided to end my life by drowning myself in bathtub.’
Olayemi Oniroyin, o wu mi ki n so itan Nick
dele ke e le kogbon igba –iponju-la-a-more ati bi e se le se awari agbara
imuniro nigba isoro. Mo pinnu lati da alaye mi duro nigba ti mo ri fiimu tuntun
eleyii ti ile ise ESPALUM Productions
setan lati gbe jade eleyii ti won pe akole re ni EYINJU ELEDUMARE.
Itan EYINJU ELEDUMARE ko yato si itan igbesi Aye Nick rara. Bi ohun kan ba tile wa to fe mu itan igbesi aye won yapa,
a je wi pe ti EYINJU ELEDUMARE tun seni loju baibai ju ti Nick lo ni.
Nick ni awon obi ti won setan ati se iranlowo
fun un, ojo ti won bi Eyinju Eledumare si ile aye ni yeye omo gborun lo. Bee
si ni enikan ko le so ibi ti baba omo wa titi omo fi sagbako osan ganagna. Bi
okan eniyan ti wule ko le koko bi okuta to, bi o ba ri ohun ti mo ri ninu
Eyinju Eledumare yoo yomi loju.
Bi omode ba logbon ori e je ka ponle, bi
agbalagba ba ni laakaye to yamura baa ba pe iru won l’Orunmila baba Agbonmiregun ko si asodun nibe rara. Ipa ti Arike Akinyanju ko ninu fiimu eleyii tun je ara oto ninu ise tiata ile Naijeria eleyii to se afihan ogbon ori tuntun ati ebun ise akoni fo fakiki ti ko see foju pare.
Aimoye awon osere lo kopa ninu sinima Eyinju Eledumare, lara won ni Muywa Ademola, Bimbo Akintola, Peju Ogunmola, Ayo Mogaji, Afeez Eniola Lateef Adedimeji. Bi eniyan ba ro wi pe awon osere inu ere ti tan, a je wi pe eni naa ni lati ri ise ti Liz da Silver, Kehinde Abimbola ati Kunle Afod se ninu sinima olokiki yii. Ojopagogo ko niidi apejuwe, nibi ti Sanyeri ati Kamilu Kompo ba ti jo lepo, o ye ko ti ye yin wi pe ko ni easy rara fun awon mejeeji. Awon wonyii ni die lara awon osere ti won kopa ninu EYINJU ELEDUMARE.
Adebayo Tijani to se APESIN lojosi ti ariwo gbale ti okiki gba gbogbo igboro lotun pada pelu ise opolo lati fi ipa tuntun lele ninu ise tiata igbalode pelu EYINJU ELEDUMARE.
![]() |
Arike omo Akin |
Ojo Aboki ti pe ni Sabo, o si ti ni iye gooro ti Gambari ti je kehin to pon. Arike Akinyanju (Eyinju Eledunare) naa ti bere ise opolo kii se oni rara. Die lara awon ise to ti kopa seyin ni OPO lati owo Fathia Balogun, OMO OLODO lati owo Adebayo Tijani, ADAJO AYE lati owo Bose Oladimeji ati ARINAKORE eleyii ti Afeez Eniola se jade. Bee si ni aimoye ise mi lo ti se jina eleyii to ti kopa ti ko ti i jade sita. Die lara won ni OMO VC ati AYE MI lati owo Bose Oladimeji.
Nick Vujicic wa agbara lati mu ala re se, eleyii ti olubori be je idunnu lati gbe ile aye. Ko ni ore kankan, sugbon o se akiyesi wi pe ife oun wa lokan awon omo wewe tori won ri gege bi alawada. Nick gba lati je ore awon omode bee lo si maa n gba won niyanju ati sise idanileko oro Olorun fun won.
Odun 2012 ni itan igbesi aye Nick Vujicic yipada. Eni ti gbogbo aye ro wi pe kole pago se bee kole alarinrin.Odun yii ni Kanae Miyahara, orekelewa obiirin gba la ti fe Nick, awon eniyan mimo si so won papo niwaju Oluwa. Igbeyawo ife awon mejeeji yii ni awon ologbon aye se alaye re gege bi ohun ti yoo wa ninu iwe itan omo eda eniyan titi lailai. Mo setan lati se afihan fidio Ife Nick ati Kanae fun yin ki e le ri idunnu nla ninu aye eni to ti fi igbakan pinnu lati gba emi ara latari igbe aye re to kun fun ibanuje. Sugbon mo ro yin ki e gbiyanju lati wo Eyinju Eledumare nikete to ba de ori igba ki e le ni oye alaye mi.
![]() |
Nick ati ebi re ni Miami |
Gege bi Larry King to je osise ile ise iroyin CNN agbaye se so nipa iriri re ninu ise iroyin, O ni ise iroyin kii se ise bojuboju, ati wi pe kii pe ki awon eniyan awujo to mo ojulowo oniroyin ati ayederu ti n paro jeun faye. Sugbon ninu ero mi, emi gba wi pe ise iroyin ko yato si ise awo. Babalawo to ba n paro, won ni Ifa won ni i pon won laso. Oniroyin to ba tori asodun fi iro kun ise opolo, iru won kii pe di oniyeye eniyan. Mo ti so fun yin nipa EYINJU ELEDUMARE, mo si ti so nipa ipa ti irawo tuntun ti nje Arike Akinyanju ko ninu fiimu naa. Olayemi Oniroyin, ti mo ba paro tabi mo so otito dandan ni ki oro Larry King se mo mi lara. O digba!
The Incredible Love Story of Nick Vujicic and His New Wife from keephopealive on GodTube.
Igbawo ni film naa fe jade?
ReplyDelete