Ninu idije Champion League to n lo lowo, ifesewonse kinni ti abala quarter final ko derun fun egbe agba boolu Chelsea pelu bi won se pade iya eleyii ti won ko fokan si lowo agbaboolu PSG ti Faranse pelu ayo meta si ookan (3:1)
Omo ilu Argentina, Ezequiel Lavezzi lo koko ja irawo Mourinho eleyii ti gbogbo awon ololufe PSG ti n beru tele latari ise opolo ti baba naa ko sagbari nipa goolu aramonda to so sawon. Sugbon nigba to ya ni Eden Hazard mu Chelsea pada bo sipo ni iseju metadinlogbon ti ere naa ti bere.
Ni nnkan bi iseju mokanlelogota ni PSG tun pada jewo fun Chelsea wi pe ile ni awon wa, ati wi pe ko sewu pelu ayo David Luiz to gba wole.
O ku die ki ifesewon naa pari ni Javier Pastore ba pa gbogbo awon omo Chelsea lekun pelu bo se so ayo naa di meta ni ile awon omo alaso buluu.
Ojo to n ro ni oro yii, ko si eni to mo iye eni ti o pada pa. Ifesewonse eleekeji yoo waye lojo Isegun to n bo yii nibi ti a ti mo tani 'Olusegun' gan-an laaarin PSG ati Chelsea ni ilu England.
Subscribe to:
Post Comments
(
Atom
)
0 comments:
Post a Comment