Smiley face

Won Ti Dana Sun Were Ajomogbe To N Lo Blackberry Ni Ipinle Ondo

Ni ojo Aje to koja yii ni isele ta a wi yii sele ni opopona Oluseyi ni ilu Ondo gan-angan nibi ti awon eniyan agbegbe naa ti danu sun were obirin ajomogbe kan ti were naa si jona teyinteyin.


Gege bi a se gbo, odu ni were yii je kii se aimo fun oloko rara. Opolopo awon eniyan ni won si mo oruko re gege bi Aya-Baba. Ibi akitan to wa ni agbegbe Oluseyi naa lo maa n je si.

Sugbon lojo Aje to koja yii ni sitori Aya-Baba ti gbogbo eniyan mo gege bi were lo yipada di ajomogbe nigba ti won fura si i wi pe oun gbiyanju lati ji omo ile iwe kan gbe salo.

Awon ti isele naa soju re fi ye wa wi pe won kan foonu Blackberry olowo nla kan mo o lowo pelu Nokia eleyii to fi n se ikeji ara. [Se mo wi pe ti eniyan ba n lo BB o gbodo tun ni Nokia kekere kan lati maa fi maintain tori pinging kii je ki batiri BB pe titi]

Aya-Baba pada jewo, o si so fun awon to mu wi pe ilu Oshogbo gan-an ni Headquarter oun wa ati wi pe mission pataki lo gbe oun wo ilu Ondo.

Oju ese nibe naa ni won ti dana sun Aya-Baba lai duro de Baba. Ki awon olopa to de, Aya-Baba ti ka bi eja gbigbe.

Gege bi Difio eka Funbi Fagun Police Division ti Ondo town,Ogbeni Emmanuel Okorie se so, O ni awon ti fi isele naa to komisanna to je oga awon to wa ni Akure leti.

Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment