Smiley face

Àdó Oloro Meji Dun N'Ile Ife Oduduwa

Àdó olóró meji kan ti dún ni agbègbè Agbedegbede tó wà ni Ilé Ifẹ̀ laaaro putuputu àná [1-7-14] ni nńkan bi ago marun-un abọ idaji.

Bi o tile je wi pe ko si emi kankan to ba ìsẹ̀lẹ̀ naa lo sugbon aimoye dukia lo sofo danu ti enikeni ko si le so iye won. Awon osise alaabo Ipinle Osun ko ti le so pato ohun to fa sababi isele buruku naa titi di akoko ti a fi se àkójọpọ̀ iroyin yii.

Sugbon ara ti n fu awon eniyan wi pe ko maa lo je ise ọwọ́ awon Boko Haram ni.

Gege bi awon onwoye nipa eto ilu se so, won ni odun 2009 ni Boko Haram bere isẹ buruku ọwọ́ won ni agbegbe kan ni Ipinle Bauchi. Ko to di wi pe won gbe aafin won lo si Maiduguri. Aimoye ilu ni won ti ranse iku si bi Kaduna, Adamawa, Yobe, Kano, Borno, Bauchi atbbl. Aimoye eniyan ni won si ti ran lo sorun eleyii ti enikeni ko le so pato iye won.

posted from Bloggeroid

Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment