Smiley face

Awon Eniyan N Sise Oluwa Oba Allah Ni Ilu Makkah

Ni ilu Mekkah, awon odo bi egberun meta (3,000) ni won ti fi ara won sile fun ise oba Allah lati maa ran awon alejo ti won n ya wo ilu Mekkah lati wa oju Oba Allah fun aanu ati idarijin.

Awon odo ti a ri pupo won ni agbegbe Kaabar nibi ti awon eniyan ti n Tawaf ni won ran awon agbalagba arugbo lowo ati awon abarapa.

Gege bi awon alase ilu Mekkah se so, won ni wakati merilelogun (24) ni awon odo yii fi n sise laibojuweyin rara. Lara ise won tun ni amojuto oju ona ki awon eniyan le raye koja daada.

Agbara adura ti sokale bayii ni ilu Mekkah. Awon eniyan lati gbogbo orileede agbaye ni a ri ni igboro Mekkah. Pupo ninu gbolohun enu won naa  lo n so wi pe okan soso ni Olorun Oba Allah.

Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment