
Awon olopa ìlu China ti fi òfin de Wo Guo ẹni odun marunlelogoji [45] latari wi pe okùnrin naa n wa mọ́to lai ni apá. Won ni bi o tile je wi pe ko ti ni ijamba moto pelu bi o se n fi ese re wa moto, sibesibe won ni o lewu gidi fun un ati awon eniyan oju popo.

Ilu Xiantao to wa ni aarin gungun China ni won ti gbe ri okunrin aramanda yii. Okunrin yii se alaye wi pe olórí pipe eda ni ohun je, o ni ọ̀sẹ̀ bi meji ni ore oun si fi ko oun ni moto. Gege bi alaye re, oni moto naa n ran oun lowo lati kiri oja re fun awon onibara.

Wo Guo ti n ta eso orisiirisii yii ni awon olopa ti lo gba niyanju lati lo gba dereba ti yoo maa ba wa mo to re.
‘He is admirable, but it’s too dangerous for him to drive. I hope he can give up driving himself and employ someone else.’ awon olopa.

Ati nnkan bi omo odun meje ni okunrin yii ti padanu owo re nigba to lo gbana elentiriki alagbara mu. Isele yii lo mu awon dokita ge owo re danu ki alaafia le de ba ago ara to ku.
posted from Bloggeroid
0 comments:
Post a Comment