Smiley face

Ilu Jamani Gbade, Won Gba Goolu, Won Si Tun Gbeye Ni Ilu Brazil

 
Ilu Germany ti gba ifi eye boolu agbaye fun igba kerin pelu bi won se ju bombu ayo kan pere sile Argentina ti gbogbo ile won si fon yangayanga lai seku nnkankan. Idunnu nla sele fun awon omo Jamani ti won wa ni ilu Brazil ati awon ti won n wo boolu naa lati Berlin ni Jamani. Nigba ti awon omo Argentina mu ekun sun loju paali bi omode ti won gba buredi lowo re. Gbogbo aworan won ni mo kojo fun igbadun yii.

Awon iroyin mii tun bo lai pe nipa idije boolu agbaye to waye ni ilu Brazil eleyii to pari lojo ketala osu keje odun 2014. E maa gbagbe lati tele mi lori ero twitter fun awon iroyin pajawiri loju opo @OlayemiOniroyin.
Mo feran ki n maa dasa 'Ise ko lowo Baba Karimo'. Eni Edumare ba ran lowo ni i jo bi ologbon loju omo araye.
Ojo Aje lonii, ki gbogbo wa pata ka ri Aje se ohun rere. Amin
Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment