Smiley face

Ki Lo Sele Lojo Ti Oba Meji Pade Ni Ilu Atlanta?: Femi Solar Jasa King Rokan Ni Ilu Amerika

Adekola Dking Rokan
Atlanta to wa ni Georgia ni ilu Amerika ni Adekola Rokan n gbe. To ba fe se faaji ni i lo si Ilu London lo re e je eja tutu legbe odo. Ko si omo naa ti o ko Juju ni ilu Amerika ti o ni fori bale fun King Rokan oba onile funfun. Gege bi iwadii Olayemi Oniroyin Agbaye, ko si iye owo ti eniyan le san fun King Rokan wi pe ko wa korin lakoko to ye ko wa ni ile ijosin nibi ti omokunrin naa ti maa n fi ohun orin agbara ihin fun Olorun Ijo Mimo eleyii ti yoo joju lati yii okan re pada. Opolopo awon eniyan lo si gba wi pe eleyii wa lara nnkan to n mu okiki ati orin King Rokan di erujeje ni gbogbo ilu Amerika.
Femi Oorun Solar [FOS] King of JasaMusic
Olayemi Oniroyin, e so fun sekaseka ki won yee binu ori. Eni Edumare ba da lola ni won pe l'Oba. King of Jasa Music ni yii. Femi omo Oladele ti kuro lomode olorin ti n lu panseke lai si duuru. Ohun orin Oba Jasa, asanyan ede to won bi oju pelu ifi-ami-ororo-yan orin to wa lori Jasa loyi irawo re pada si Oorun, oorun naa tan o si kari aye. Ilu Nigeria ni Femi Oorun Solar n gbe. Pretoria to wa ni South Africa lo ti n sere lopin ose lati lo se faaji fun awon alafe eniyan. Ojo ti omo Oladele ba fe se afihan ori tuntun ti won pe ni Musical Exhibition ni  oun nikan n wo baalu  nla ti Virgin Atlantic lati lo salaye ohun ti won pe ni Jasa ni ilu Amerika fun awon ti o ti jasi.
DKing Rokan + King of JasaMusic: Ijo Oba

Sugbon ohun kan sele lojo kan ni ilu Amerika, ojo ti King Rokan pade Oba Jasa ninu ile orin re to wa ni Atlanta. Gongo so! 'Ile mi ni mo wa. iwo boy yii, o le ba mi ta game yii.' King Rokan n fohun sile fun FOS. Femi Oorun naa n da lohun oni, 'Baba, e gboju mbe. Oorun ni Solar ko ye yin ni? Gbogbo ibikibi ni oorun ti n joba; koda, ko je Slovenia mo n Jasa mi lo ni.'


Oba meji korin papo okiki kan. Orin oba si ti pada di Ija Oba. Ha! se Ija Oba ni mo so? E dakun, Ijo Oba ni mo fe wi. Beeni, Ijo Oba lati owo Adekola Dking ati Femi Solar Oorun. Orin oba ko pariwo, Ijo oba jelenke ni. 

E ku faaji.
E DOWNLOAD IJO OBA NIBI


Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

2 comments:

  1. Solar go on. Yankee boi. we dey feel.Ko si eni to le fi owo bo ogo oorun, ko si eeni to le fi owo bo ogo osupa. #naija pride

    ReplyDelete