Lopin ose to koja [3-8-14], Ilu Oshogbo ni King Wasiu Ayinde KWAM1 wa nibi ipolongo Ogbeni Rauf Aregbesola, eni to n dije lati je gomina ipinle naa fun igba keji.
Leyin ti Ayinde kuro nigbagede ipolongo ni awon kan lo dena de, ti won si bere si ni da ibon bo moto Olu Omo of Lagos. Sugbon ori eye ko peye; oko taa so mope lope so pada.
Adia fun Orunmila lojo to wa laaarin awon ota. Won ni Orunmila, awon ota ni yii niwaju. Orunmila ni iwaju loka foro si ti fi n pani. Won ni Mr Orunmila, awon ota ni yii leyin. Orunmila ni eyin ni akeeke fija si ti n fi n joni bi ina. Ina ti won ba da de gunnugun, eye ti o ni star ni won fi n sun je.
O seese ko je wi pe ayajo ti Wasiu lo ni yii ti ota ibon ko fi baa. Nitori titi di akoko yii, ko ti si aridaju iroyin nipa ohun to ko K1 yo. Baba Yomade lo wa moto fun ara re, kosi si osise alaabo pelu re ni akoko isele naa.
0 comments:
Post a Comment