Awon omo agbaboolu Jamani pada fi eyin awon omobirin egbe agbaboolu Nigeria, Falconets janle pelu ami ayo okan si ofo (1-0) ninu asekagba idije boolu agbaye ti awon obirin ti ojo ori won ko koja ogun odun.
Asekagba to waye ni ilu Canada lo n se igba keji ti ilu Jamani yoo maa na Nigeria sare. Egbe agbaboolu Jamani naa lo na Naijeria ninu asekagba to waye ni odun 2010.
Odindi Ogofa iseju (120mins) ni Germany ati Nigeria fi ta tan ni papa isere Montreal's Olympic ko to di wi pe Lena Petermann dana sun Nigeria leyin iseju mejo ti won bere afikun akoko ( Extra time).
0 comments:
Post a Comment