Sebi awon Yoruba loni eni ba dupe ore dandan ni ko gba
plenty ore lojo mii. Idi ni yii ti mo fi n dupe lowo awon Olooto Yoruba
Dun lori FACEBOOK fun atileyin ti won n se fun olayemioniroyin.com.
Ninu
Egbe Yoruba Dun yii ni Ogbeni Kingforeal Arisekola ti te pepe idibo bi
igba ti Jega ba gbe eto idibo kale. E ma je n tan yin, opolopo awon
eniyan ti ko seeka ni won ni Ogbeni Aregbe somoluabi pupo, won si ni oun
ni awon fe gege bi gomina Ipinle Osun. Awon eniyan die ni won se
t'Omisore nigba ti awon kan bi melo kan ko fara mo awon mejeeji rara.
Ti a ba ni ka tele ero awon eniyan lori YORUBA DUN, o dabi eni wi pe Baba Kabiru ni o pada je gomina fun igba keji.
Bi
o tile je wi pe eto idibo ori ayelukara lasan niyii, sugbon iru nnkan
bayii maa n fi ero awon eniyan han eleyii ti pupo re maa n je otito ninu
ohun ti o pada sele gan-angan lojo idibo.
Eyin naa le ye idibo naa wo [NIBI].
E si ma gbagbe lati tele mi lori Twitter, @OlayemiOniroyin loju opo ti mo n lo. E se pupo.
0 comments:
Post a Comment