Sebi bi a se n yo so naa ni a n yo gbo. Iroyin tuntun to kan wa eleyii ti ile ise iroyin CNN agbaye tun ti fidi re mule ni wi pe awon igbimo alase agba ile Nigeria ti i ni ipade po pelu awon asoju Boko Haram nidakonko nipa ati tu awon omo Chibok bi igba (200) ti won gbe salo bi igba ti eye asa gbe oromadie leyin iya re sile.
Ohun kan pataki ti awon asoju Boko Haram n beere fun naa ni idasile awon eniyan won bi ogbon (30) to wa latimole eleyii ti Kabiru Sokoto to je oga nla awon Boko Haram naa wa lara won.
Ipade bonkele bi meji lagbo wi pe won ti ni. Ohun kan ti n fa ifaseyin naa ni afikun alaye awon omo Boko Haram to wi pe: " E so fun Jonataanu, a ko le ko Igba omo kale, ki Jonathan wa ko ogbon eniyan fun wa, bisineesi ti ko mu opolo dani gbaa ni.
Oba Allah loke gan-an ko ni like ka se bee. Ohun ta maa se ni wi pe, okan fun okan lo maa je. A maa ko ogbon omo sile, Jonathan naa ma ko awon tia ti won je ogbon(30) naa sile".
Aba buruku yii ni Aare Jonathan kojale lati gba wole. Nitori ohun ti awon igbimo Jonathan n beere fun ni gbogbo awon omobirin bi igba (200) naa ki awon naa si da omo Boko Haram bi ogbon to wa lowo won sile.
Sebi gba fun Raji nile naa ni gba fun Gbada loko. Omo oko ti o ba je buredi Agege yoo fi isu esuru ranse sile. Eni to ba dami siwaju dandan ni ko tele tutu.
Ati wi pe oro naa dabi Aaya ati Ogungbe. Aaya gbon, Ogungbe gbon; Aaya n tiro, Ogungbe n bere.
Se ogbon(30) Boko Haram lo wa ni ahamo awon alase agba ile Nigeria?
Olayemi Oniroyin, ohun ti won ba so jade lawa n so di iroyin. Sugbon ti sorosoro ba n soro, eni ko ranti eni to moo gbo.
Ologbon eniyan ni iran Yoruba, e gbo ohun ti won so. Won ni ti eru (slave) ba n saare (aisan), won a ni o tun gbese re de. To ba je omo oba ni, won a ni ki won fomitoro eja si i lenu".
Awon ologbon ni alaye mi ye. Omo Yoruba atata lo le mo itunmo oro to ba takoko.
O digba!
Subscribe to:
Post Comments
(
Atom
)
0 comments:
Post a Comment