Awon Yoruba ni bi onirefin ko ba fingba mo, eyi to ti fin ko le parun laelae. Okan lara awon gbajugbaja ewi akosori ile iwe alakobere nigba kan ri ni yii, eleyii ti opolopo awon agbalagba aye ode oni ka ninu iwe Alawiye ti won koko te jade lodun 1943.
Nje eyin si ranti bi?
Ise l'ogun ise
Mura s'ise ore mi
Ise la fi n'deni giga
Bi a ko ba reni feyin ti
Bi ole la'nri
Bi a ko ba reni gbekele
A tera mo'se eni
Iya re le lowo lowo
Baba re le lesin lekan
Bi o ba gbo'ju lewon
O te tan ni mo so fun o
Ohun ti a ko ba ji'ya fun
Se kii le pe lowo
Ohun ti a ba fara sise fun
Nii pe lowo eni
Apa lara
Egunpa niyekan
B'aye ba n'fe o loni
Bi o ba lowo lowo
Aye a ma fe o lola
Tabi ki o wa ni'po atata
Aye a ma ye o si terinterin
Je k'o de'ni tin rago
Aye a ma yinmu si o
Eko si'nso ni d'oga
Mura ki o ko dara dara
Bi o si r'opo eniyan
Ti won f'eko s'erin rinrin
Dakun ma f'ara we won
Iya n'bo fun'omo ti ko gbon
Ekun n'be fun'omo to nsa kiri
Ma f'owuro sere ore mi
Mura si'se ojo'nlo.
Subscribe to:
Post Comments
(
Atom
)
0 comments:
Post a Comment