Oba Lamidi Adeyemi III |
Leyin ayeye ojo ibi odun metadinlogorin (77) Oba Lamidi Olayiwola
Atanda Adeyemi III to waye laipe yii, awon ojongbon tun ti pawopo fi oye
Dokita da Alaafin Oyo lola.
Ayeye yii lo waye l'Ojoru to koja yii nibi won ti n se
ikojade awon omo akekoo gboye ile iwe Ifafiti Afe Babalola to kale si
Ado-Ekiti. Iru ayeye yii ni yoo je eleeketa iru e ti o waye lati igba ti
won ti fi ile iwe giga naa lole lodun 2009.
Lara awon eniyan ti won da lola lojo naa ni olori ijo
Aguda eka ti ipinle Sokoto, Bisoobu Mathew Kukah, Kofeso Attahiru Jega
to je alaga egbe INEC tele ati onidajo-feyinti Emmanuel Ayoola Babalola.
Gege bi alaga igbimo oludari ile iwe naa, Ojogbon
Iyorwuese Hagher se so, o ni awon eniyan ti awon dalola yii lo je awon
ti won ti kopa ribiribi ninu idagbasoke igbe aye awon eniyan awujo.
Eleyii to se apejuwe won gege bi awon eni iyi ateye.
Alaafin nikan o darin, die lara awon ayaba ati igbimo
Oyomesi koworin pelu oba to je nikete ti Gbadegesin Ladigbolu II goke
aja. Koda, won tun ya foto pelu awon oloye nigba ti won pada saafin baba
ti mbe lode Oyo.
0 comments:
Post a Comment