Awon olopaa fako yo! Won gba owo inu saka nla mesan-an pada lowo awon adigunjale banki. Olayemi Olatilewa
Awon olopaa digboluja ti won gbogun ti iwa odaran gba
obitibiti owo naira pada lowo awon adigunjale ti won dena de oko banki
Diamond niluu Pota.
Awon igara olosa bi meje yii ni won dena de oko banki
agboworin ti eka ile ifowopamo Diamond to wa ni Trans Amadi, eleyii to
kale si ilu Port Harcourt, l'Ojobo ose to koja ni nnkan bi aago marun-un
irole.
Owo kan ti iroyin isele naa kan awon olopaa lara ni
won ti be sita. Won le awon ole naa ba, itaporogan naa si di "faya fo
faya" laaarin olopaa digboluja ati awon gbewiri.
Leyinoreyin, awon ole naa salo nigba ti won fi oko ati owo ti won jigbe sile seyin.
Awon owo yii to je asan egberun kan naira ni won kun inu baagi "Ghana Must Go" mesan-an.
Alarinna ile ise olopaa ipinle Rivers, ogbeni Ahmad
Muhammad je ri si isele naa. O ni ohun to mu awon se aseyori ko ju bi
awon se yara dide lo nikete ti iroyin naa wole.
Ohun ti a tun gbo ni wi pe, o seese ki agbeyinbeboje kan wa ninu banki, lara awon osise. Eleyii to n fun awon ole naa lowo.
Ogbeni Ahmad so wi pe awon olopaa si n ba iwadii won lo lati ri i daju wi pe owo te awon odaran naa ti won salo.
0 comments:
Post a Comment