Smiley face

Ayajo awon tisa agbaye dun nipinle Ekiti: Fayose fi moto se sadaka fun awon tisa

Ni ojo Aje to koja yii ni ayajo ojo awon olukoni agbaye eleyii ti won lo lati fi bu ola, iyi ati eye fun awon tisa kaakiri agbaye.

Sugbon ni ipinle Ekiti, nnkan tun rosomu fun awon tisa pelu bi gomina ipinle naa se fi awon oko tuntun aganran KIA da awon kan lola latari ise takuntakun won ninu ise olukoni.

Gege bi oludamonra fun gomina Fayose nipa oro to n lo lowo ati iroyin ayelukara, Ogbeni Lere Olayinka, se atejade awon oruko tisa ti won ri ire oko KIA SOUL gba lowo gomina.

Arabirin Akindele Mary lati ile iwe St John's Pry, Emure Ekiti lo gba ami-eye tisa ile iwe alakobere to pegede ju lo. Nigba ti Ogbeni Adeola Joseph lati Ijaloke Grammar school, Emure Ekiti gba ami-eye tisa ile iwe girama to dara ju lo.

Eyi to se eleeketa re ni ami-eye oga ile iwe to sise re bi ise ju lo fun ipinle Ekiti, Arabirin Alabi Racheal Eyiyemi.

Gbogbo won pata ni won gbe oko tuntun rele ti won si n korin yin gomina Peter Ayodele Fayose, eni ti inagije re n je Osoko, gege bi gomina to lenu ju lo nile Naijiria.

Ajo United Nations Educational Scientific and Cultural Organization (UNESCO) naa ko gbeyin ninu ayeye ayajo awon tisa ti odun 2015. Ninu alaye won, won temu mo pataki ironilagbara awon tisa gege bi ona kan lati mu won se aseyori to peye ninu idagbasoke eto eko aye ode oni.
Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment