Owo awon olopaa ilu London ti te Diezani Alison-Madueke to je minisita fun epo robi nigbakan labe isejoba Goodluck Jonathan. Alison-Madueke ati awon merin kan ni owo te laaro ojo Eti to koja yii pelu esun Jegudujera, riba ati sise owo ilu mokumoku.
Ogbeni Joseph Abuku to je alukoro fun ile ise asoju ijoba ile Biritiko ni ile Naijeria jeri si i wi pe lotito ni awon agbofinro ilu London ti gbe awon eniyan marun-un kan ti won je omo Naijeria laaro ojo Eti. Sugbon okunrin naa ko lati daruko awon eniyan ti owo te naa.
Laaarin wakati meji ti won so Alison-Madueke sinu gbaga niluu London, awon ajo EFCC gbera lo fi agadagodo ti ile madaamu naa pa eleyii to wa ni Asokoro niluu Abuja.
Orisirisi awuyewuye lo ti n jeyo lori ero ayelujara nipa bi won se mu Alison-Madueke.
Awon kan ni Buhari lo wa nidi isele naa nigba ti awon kan gba wi pe oseese ko je lara iranwo ti awon ilu okeere pinnu lati se fun aare Buhari latari awon abewo re si awon olori orileede agbaye ni awon akoko kan seyin.
Saaju igba yii, lara atejade to te Olayemi Oniroyin lowo fi han wi pe iye owo bi bilionu mejilelogbon owo dola ile Amerika ($32b) lo poora ninu asunwo ile ise epo NNPC ile Naijeria ni akoko ti Alison-Madueke je minisita fun epo robi.
Ju gbogbo re lo, nigba ti o fi di asaale ojo Eti kan naa ti won mu Alison-Madueke, awon olopaa ilu London tun pada gba beeli re nipase oniduro to rese wale.
Sugbon won ti gba iwe irinna re, won si tun ni ko pada fara han ni Charin Cross Police Station lojo Aje, ojo karun-un osu kewaa odun yii lori esun kan naa ti won mu fun.
Ojo to n ro ti o ti da kosi eni moye eni ti o pa. Iroyin to jade nipa bi won se mu obirin akoko ti o je minisita fun epo robi ti bere si ni da aibale okan sile fun pupo lara awon igbimo ijoba ana.
Subscribe to:
Post Comments
(
Atom
)
0 comments:
Post a Comment