Mercy Aigbe-Gentry, okan ninu awon oserebirin onirawo meje ile Naijiria, dana ayeye ojo ibi to peleke fun oko re, Lanre Gentry, eni to pe omo aadota (50) odun lose to koja.
"Eni ma segbeyawo a se gudugudu meje" l'Oritse Femi ko morin. Sugbon nipa ti Mercy Aigbe, "eni maa soko onitiata yoo se gudugudu meje pelu yaaya mefa lomobirin to je omo bibi ilu Edo ko lorin lati fi se aponle oko re nibi ayeye ojo ibi re to ko.
O salaye bo se nira fun awon okunrin lati gbe po pelu awon obirin onitiata. Sugbon nipa suuru ati ife otito, o ni oko oun ko ja oun ju sile rara bi aso to ti gbo.
Bi o tile je wi pe awuyewuye kan seyo ni awon igba kan wi pe oko Bimbo Akinsanya ti oun naa je oserebirin ni Mercy Aigbe jagba to si so di oko tie losan gangan.
Sibesibe, Lanre Gentry ko sai tako iroyin naa nigba to n se alaye wi pe oun ati iyawo oun akoko ti ko ara awon sile fun igba pipe saaju ki oun to pade Mercy Aigbe.
Mercy Aigbe naa ti ni oko kan tele ri, eleyii ti igbeyawo naa fori sanpon leyin omo kan. Mercy Aigbe salaye wi pe iya oko oun akoko korira oun nitori wi pe awon kii se eya kan naa pelu won. Eleyii lo sokunfa bi igbeyawo naa se tuka yangayanga bi eyin ti won solu apata.
Ju gbogbo re lo, ojo ibi Lanre oteyii kamomo pelu orisiirisii oro adidun ati iwuri ti aya re fi kii ku oriire ayo aadota odun to ba a laye.
"Lai fi oro si abe ahon so, ko rorun lati soko onitiata/onisowo. Sugbon okunrin yii je eda oto gedegbe. O je eni to ni agboye, o si je oluranlowo pelu.
Nigba mi-in ti gbogbo e ba su mi, ti mo ti fe ropin, o je enikan ti mo maa n ri legbe mi to si maa n gba mi niyanju ati tesiwaju.
Mo dupe gidigan, adun ife mi. Bo o se le lodun lonii, Edumare yoo tun bo ma da o si fun mi, ninu alaafia, emi gigun ati ibukun yanturu loruko Jesu. Titi lae ni i ma nife re, ade ori mi." - Mercy Aigbe-Gentry
Home / Uncategories / Mercy Aigbe pe oko re keji to fe ni adun ife otito: Oko Aigbe pe eni aadota odun laye
Subscribe to:
Post Comments
(
Atom
)
0 comments:
Post a Comment