Awon Yoruba bo, won ni taa ba dojo, ojo a pe. Baa ba dosu, dandan ni kosu o ko.
Ojo
ketadinlogun osu yii (17/11/15) ni ile ise redio ti n se igbelaruge ede
ati asa Yoruba, Oodua Voice Radio, di kiko jade bi omo tuntun leyin
okiki re to ti gbalegboko.
Gege
bi iwadii Olayemi Oniroyin Agbaye, ile ise redio ti yoo ma fonrere lori
ero ayelujara yii ni won se idasile re fun itesiwaju asa, isokan ati
isese awon omo Yoruba to wa loke okun.
Ayeye
ifilole naa lo waye ni Durning Hall Community Centre, Earlham Grove,
Forest Gate niluu London nibi ti oludari egbe Oodua Peoples' Congress,
Otunba Gani Adams ti fi iwure awon agba si redio naa seti gbogbo araye.
Ogbontarigi
oniroyin omo Naijiria to fi Biritiko sele, Ogbeni Fatai Ogunribido, se
apejuwe Ogbeni Gani Admas gege bi apeere idagbasoke ati igbelaruge kan
pataki to deba asa ati isese Yoruba.
Kete
ti won si ile ise redio yii,ni Muyiwa Adekunle ti gbogbo eniyan mo si
Bubble Master ati Lasley Oladigbolu kanlu ori afefe ti awon eniyan
kaakiri ilu London ati agbaye si bere si ni jasi oju opo Oodua Voice
Radio, www.ooduavoice.com lati maa je igbadun won ni perewu.
Foto: lati owo Wale Ojo-Lanre
0 comments:
Post a Comment