Smiley face

Idi pataki meta ti ko fi ye ka maa fi ehin je eekanna



1. Ehin le yingin tabi ki die kan lara ehin wa: Nigba mi-in ti a ba n gbiyanju lati fi ehin ge eekanna wa, ehin wa le lura won lojiji, eleyii si le fa ki ehin yingin legbe kan tabi ki die lara re kan danu.


2. Erigi enu wa ninu ewu: Bakan naa, fifi ehin je tabi ge eekanna wa le se akoba fun erigi. Okan ninu iriri awon dokita onitoju ehin fi ye wa wi pe nigba ti eniyan ba n gbiyanju lati fi ehin ge eekanna, oseese ki eekanna naa ha si aarin ehin, eleyii to le se akoba fun erigi enu wa.

3. O le fa aisan si ago ara wa: Awon idoti to wa ni abe eekanna, eleyii to kun fun kokoro aifojuri le sakoba nla fun ilera wa to ba se bee bo sinu enu wa. 

Lakotan, Awujo wa tile ka asa ifehin ge eekanna gege bi iwa obun eleyii ti ko bojumu. E je ka yago fun iru iwa bee. E je ka wa obe sekele ti aa ma lo, eleyii ti enikeni ko ni ba wa pin lo, lati fi maa ge eekanna wa nigba gbogbo.

Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment