Smiley face

Ireti Odegbami ja sofo lati di aare FIFA agbaye


Ireti Odegbami ja sofo lati di aare FIFA agbaye

Segun Odegbami
Opin de ba erogba ati ala ogbontarigi agbaboolu Naijiria nigba kan ri, Segun Odegbami lati di aare ere boolu agbaye ti a mo si FIFA. Ijakule yii lo waye nigba ti awon ajo ere boolu ile Naijiria ko lati se iwe atileyin won fun un. Oru Monde to koja yii ni gbedeke ti ajo FIFA da fun awon oludije lati fi iwe atileyin yii ranse, eleyii ti yoo mu won gba won wole gege bi oludije to koju osuwon.

Bi o tile je wi pe ajo ere boolu ile Naijiria ti n fenu so wi pe gbagbaagba ni awon wa leyin agbaboolu to gba boolu metalelogun (23) sawon ni akoko ti n gba boolu fun orileede Naijiria, sibesibe ileri atileyin naa ko si ninu akosile kankan.

Gege bi  adari olupolongo ibo fun Odegbami, Ade Adeagbo se so.  O ni awon orileede bi marun-un lo ye ki awon ti gbawe atileyin yii fun Odegbami, eni ti inagije re n je Mathematical.  Sugbon o soro fun awon lati ri iwe naa gba ni awon orileede yoku lai se wi pe tile baba re gan-an ti te lowo. Sebi awon Yoruba nile lati n keso rode.

Gege bi oro Adokiye Amiesimaka, eni ti oun naa gba boolu fun ile Naijiria nigba kan naa pelu Odegbami so wi pe, ajo ere boolu Naijiria (NFF) ko figba kankan se atileyin fun Odegbami; maa jo lo mo n weyin re ni won fi oro agbaboolu Shooting Star laaarin odun 1970 si 1984 se.


"O ye ki Odegbami gan-an mo lokan re wi pe yoo soro fun-un lati ri atileyin ajo NFF gba. Eniyan ti yoo je aare FIFA agbaye ni lati je okan pataki ninu ajo ere boolu ilu re. Odegbami ko di ipo kankan mu ninu ajo NFF, ba wo lo se fe se to fe yege? Ore mi ni Odegbami, o koju osuwon lati di aare FIFA sugbon ko ta opon ayo oselu re daada", Amiesimaka fi kun oro re bee.


Aare ere boolu Naijiria, Ogbeni Amaju Pinnick so wi pe ebi isele naa kii se lati owo ajo NFF rara bi ko se Odegbami. O ni ohun to fa idiwo fun Odegbami ni aijafafa re lori eto igbese lati di oludije fun aare FIFA agbaye.

Odegbami, eni odun metalelogota (63), ni oun ti gba fun Olorun pelu gbogbo ohun to waye. Bakan naa ni oun ti tesiwaju pelu igbe aye oun fun ojo rere to n wa niwaju oun.

Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment