Niluu Ilorin: "Awon osise mefa ti ku, awon kan wa nile
iwosan"- Akowe egbe osise
Gov. Abdulfatah Ahmed |
Awon osise ajo olomi ti ipinle Kwara
tu jade lojo Isegun to koja yii niluu Ilorin nigba ti won fi ehonu won han nipa
owo osu won eleyii ti ijoba ipinle naa ko lati san lati inu osu keje seyin.
Yato si owo osu won, awon owo ajemonu
kan naa tun wa lati ibere odun yii ti a gbo wi pe awon osise naa n beere lowo ijoba eleyii to
je wi pe bakan naa lomo se sori pelu owo osu ti won o ri gba. Eleyii to tun se
eleeketa iru e ni awon osise to ye ki won ti ni igbega lati inu odun 2012
sugbon ti igbega naa ko waye.
Awon osise ajo olomi ipinle naa ni won
gbarajo labe egbe kan ti nje Amalgamated Union of Public Corporations, Civil
Service Technical and Recreational Services Employees (AUPCTRE), eleyii to je ti
eka ajo olomi ti ipinle Kwara.
Awon osise yii ni won gbegi dina geeti
abawole to wa leka ile ise ijoba naa nigba ti won fi ehonu won han eleyii to
waye fun aimoye wakati.
Nibi ifehonu han naa ti n waye ni ati
ri awon osise kan ti won gbe orisiirisii akole dani eleyii ti die nibe wi pe:
"E san owo osu wa o", E fun wa leto wa", E ma foju gongosu wo
wa, awa o go o"; "Ti eyin ba ni e ko ni sanwo, awa gan-an o ni
sise".
Gege bi olori egbe osise eka ti ajo
olomi ipinle Kwara, Ogbeni Murtala se
so. "Aimoye leta ni ati ko si awon alase pelu ijoba sugbon to je wi pe ibi
pelebe naa ni awon abebe ti a n ju soke naa fin in lele nigbogbo igba. Awa osise
ti gbiyanju oun ti a mo, igba ti won sun wa kangiri la tu jade".
Gege bi oro Ogbeni Murtala, o ni ki i
se wi pe idunnu awon lo je bi awon se duro sinu oorun lai lounje ninu, sugbon
ni kete ti ijoba ba ti dawon lohun awon nnkan ti awon beere fun dandan ni ki
awon pada senu ise lai fi akoko sofo.
Akowe egbe osise, Ogbeni Saliu Sulaiman
naa ko sai so ero tie naa fun awon oniroyin. O ni isoro ti awon ni ni wi pe
ijoba o ka won kun rara.
A tile gbo wi pe awon osise yii fun
ijoba ipinle naa ni gbedeke ojo merinla lati dahun awon ibeere won saaju ki
ifehonuhan naa to waye. Sugbon ojo merinla naa ti koja eleyii to fa bi gbogbo
osise naa se tu yaaya soju popona bi ero Mecca.
Gege bi afikun oro enu akowe naa, o ni
awon osise bi mefa ni won ti padanu emi won bayii nigba ti awon kan wa nile
iwosan latari wi pe won ko ri owo toju ara won botito ati botiye.
"Pupo ninu awon osise ajo olomi
lo je wi pe ese ni won rin wa sibi ise nijoojumo latari wi pe ko sowo lapo won ti
won le fi wo moto akero. Bakan naa ni won ti le awon kan kuro nile latari wi pe
won o ri owo ile san fun awon onile won".
Leyin isele to
waye yii ni oluranlowo agba fun gomina
ipinle Kwara nipa eto iroyin, Dr Muyideen Akorede fida awon oniroyin loju wi pe
ijoba yoo sa gbogbo ipa ati agbara re lati pase ohun ti awon osise naa n beere fun,
ti alaafia yoo si pada joba.
0 comments:
Post a Comment