1 E yee sa ara
yin sinu oorun koja bo ti ye lo. Paapa julo, e sora fun awon oorun lati bi ago
mewaa aaro si ago meji osan. Orisii oorun yii a maa mu ki awo eniyan o sa.
2. E ri wi pe e n
se imototo awo ara yin nigba gbogbo. E yago fun awon ose alagbara to le mu awo
yin maa bo.
3. Ounje lore
awo. Eri daju wi pe e n je awon ounje to peye. Awon ounje bi efo ati eso yoo se
iranwo fun awo ara yin gan-an.
4. E yago fun
siga ni mimu. Iwadii fi ye wa wi pe siga a maa je ki awo eniyan hunjo. A si maa
mu ni dabi arugbo laipe ojo.
5. Ti eniyan ba n
fi ara re sise ju bo ti ye lo, o le se akoba fun awo ara bakan naa.
6 E ri wi pe e n
mu opolopo omi. Opolopo omi dara ni mimu fun itoju awo ara.
7. E ri daju wi
pe e n fi omi boju yin ki e to sun lale ati igba ti e ba ji laaaro. Sise awon
nnkan bayii loorekore a maa je ki oju yin jolo bi oju omo tuntun jojo lo.
8. E je ki a maa
se imototo foonu wa. Paapa julo awa ti a n lo glass touch-screen. Aimoye kokoro
aifojuri lo le wa lara foonu naa eleyii ti o le sakoba fun awo ara wa. A le maa
lo Clorox Disinfecting Wipes lati maa nu oju foonu naa nigbagbogbo.
10. Fun awon
obirin, e ri daju wi pe e n fo gbogbo atike, itoju ati itote to wa loju yin ko
to di wi pe e bo sori beedi lati sun lale. Aimoye orisii eroja ni won fi se iru
awon nnkan bayii to je wi pe o le sakoba fun awo ara eni to ba peju bo ti ye lo
lara.
11. Bakan naa,
fifi omi gbigbona to gbona lagbona ju we le se akoba fun awo ara wa. Paapa ju
lo fun awon ti ojo ori won ti le ni ogoji odun.
0 comments:
Post a Comment