Smiley face

Okiki fi Oore Ofe gbe Femi Solar jade: Fidio orin tuntun yii leku!

Femi Solar King of JasaMusic
Femi omo Oladele ti gbobo eniyan mo si Femi Solar ti fi gbogbo awon ololufe re lokan bale pelu fidio orin re tuntun to pe ni GRACE nigba to n fi die ninu fidio naa to won lenu won.
Gege bi alase Sunshine Jasa Band se so, o ni kesekese ni awon eniyan ti n ri ninu ka se agbekale fidio orin to joju-n-gbese. O ni awo orin GRACE yii ni a le se apejuwe re gege bi kasakasa to je "godfather" kesekese.

"Dare Zaka lo ya fidio orin tuntun naa. Fun awon to ba si mo Dare Saka pelu awon fidio to n ti n sebo seyin, o ye ke e gba pelu mi wi pe ojumo kan ara kan lo fi n sise opolo. Ki ise eleyii tun le yato laaarin agbo amuludun agbaye, a tun se amulo awon ohun kan ti enikeni ko lo ri ninu fidio orin. Ko ni wu mi ki n so gbogbo re bayii, sebi eni a n gbe iyawo bo wa ba, won ni kii gbe ori iganna woran", Solar fi kun alaye re bee.

Okiki Films ni yoo gbe fidio orin naa jade nigba to ba jina tan. Olayemi Oniroyin ni o kede re nigba to ba gori igba. Eyin ati idile yin ko si ni padanu OORE OFE nigba to ba doju iworan yin. Amin

Eyin naa le Download itowo fidio orin Solar ti ko ni pe jade nibi:

Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

3 comments:

  1. Nice one Solar. Nice Video

    ReplyDelete
  2. Okiki re ko ni womi, oorun re ko ni wookun, gbogbo igi ti elegbede ba fowo ba, didun nii dun. Ire oo

    ReplyDelete
  3. I really love this dope called jasa king ( femi solar) nic video

    ReplyDelete