Won fadi omo odun meji ya niluu Abuja
Olayemi Olatilewa
Omokunrin eni odun merindinlogun (16) kan ti lo foju ba ile ejo niluu Abuja leyin asemase pelu omobirin, eni odun meji (2) kan.
Omokunrin eni odun merindinlogun (16) kan ti lo foju ba ile ejo niluu Abuja leyin asemase pelu omobirin, eni odun meji (2) kan.
Iroyin yii lo jade nigba ti olupejo, ogbeni Adama Musa, eni ti n soju ile ise olopaa n se alaye naa niwaju ile ejo Gudu Upper Area Court to kale siluu Abuja.
Ogbeni Musa n so fun ile ejo wi pe, ogbeni Samuel Zakka ti n gbe ni abule Pegi to wa ni Kuje lo mu esun naa to ile ise olopaa wa lojo kejilelogun osu kesan-an odun yii.
Ogbeni Samuel Zakka lo salaye fun awon olopaa wi pe odaran naa tan omo re, eni odun meji lo sinu ile kan ti won on ko lowo eleyii to lo n ba omo naa se asemase nipa titi ika bo inu idi omodebirin naa.
Awon olopaa se iwadii oro yii, won mu omobirin kekere yii lo si ile iwosan fun ayewo lati mo okodoro oro. Abajade si fi ye won wi pe lotito ni asemase waye loju ara omodebirin naa.
Igba ti omokunrin odaran yii n duro niwaju ile ejo, oun to wi naa ni wi pe oun o jebi awon esun ti ile ejo fi kan-an.
Nibayii, Onidajo Umar Kagarko ti ni ki won gba beeli odaran naa pelu egberun lona ogorun owo naira(N100, 000) pelu oniduro to lokun-undi, to si tun je olugbe ilu Abuja. Nigba ti won sun igbejo naa di ojo ketadinlogun osu kejila odun 2015.
0 comments:
Post a Comment