Komisanna awon olopaa ipinle Ogun, Ogbeni Abdulmajid Ali ti kede wi
pe,ile ise olopaa ipinle Ogun ti wa ni imurasile lati gbogun ti iwa
idaran to seese ko suyo lasiko poposinsin odun taa wa yii.
Ninu oro Ogbeni Abdulmajid, eleyii to se ni olu ileese olopaa to wa ni
Eleweran niluu Abeokuta, ibe lo ti n ro awon ti won ba fe wuwa idaran
lati kowo omo won baso nitori ileese olopaa ipinle naa yoo wa loju ise
losan ati loru.
Bakan naa lo tun fi kun wi pe, awon ofin to de banger si wa sibe digbi, enikeni ti owo ba te yoo fimu danrin.
Ogbeni Abdulmajid tun salaye siwaju wi pe, iwa idaran gbaa ni ki awon
kan maa gbegi dina lati gbowo odun tabi ki won maa ti popona pa nitori
ayeye odun ti a mo si Carnival.
O ni awon nnkan bayii ni ileese olopaa ko ni faaye gba rara.
"Esun idigunjale, ni esun ti ile ise olopaa yoo fi kan enikeni ti owo ba
te wi pe o gbegidina, to si n fi tipatipa gbowo odun lowo awon eniyan.
Ile ise olopaa ipinle Ogun ko ni foju ire wo enikeni ti owo ba te
rara," Ogbeni Abdulmajid fi kun alaye re bee.
0 comments:
Post a Comment