Orisiirisii ara
ni awon omo olorin igbalode maa n da lagbo ere orin. Iru ara bee ni bi ki won
bo aso lorun ki won si ju si aarin ero onworan. Awon mii a maa bo alakorun danu
soju agbo lati fi ife han. Nigba mii ewewe, won maa da bi oti tabi omi inu ike
si awon ero ti n je igbaladun won loju agbo ariya.
Iru asa yii naa
ni Dafidi omo Adeleke ti gbogbo eniyan mo si Davido da lara lagbo ere re kan ni
Ilu Burkina Faso. Alase ile ise orin HKN da omi inu ike si ara awon ero onworan
nibi o ti n korin. Nibi ti Davido ti n fo soke ti n yo bi eni iya re bimo
tuntun ni maanu giripa kan ba jade wa ba a lori pepe laaarin awon ero.
O gba
omo baba olowo laso mu girigiri, bee ni i gbo jigijigi, to si n bi leere idi to
fi n da omi si oun lara. Opelope awon osise alabo omokunrin olorin naa, ese nla
rigidi ti maanu naa gbe soke ko ba sokale sori gongo imu Davido baba Imade nibi
o ti n jo Skelewu pelu sokoto re to gbe si bebere-idi.
0 comments:
Post a Comment