Awon
eniyan meta kan ni ile ejo Majisireeti ti n joko niluu Ilorin, nipinle Kwara ti
ni ki won lo fi won pamo na lori esun ipaniyan ti won fi kan won. Awon eniyan
meta naa ni Abubakar Dambo, Toyin Akanbi ati Fatai Baba, eleyii ti won fesun
kan won wi pe won seku pa Afolabi Fasasi.
Gege
bi asoju ile ise olopaa to duro gege bi olufisun nile ejo se salaye. O ni lojo
keji osu kejila odun 2015 ni okunrin kan ti oruko re n je Danfulani Abdullahi lati
agboole Balogun Fulani to wa ni ilu Ilorin wa fi isele naa to ile ise olopaa
leti. Abdullahi so fun awon olopaa wi pe, nigba ti oun n gbiyanju lati kirun ni
mosalaasi Opomalu ni oun kofiri awon kan ti n sare girigiri tele omokunrin kan
ni ikorita Opomalu ni oju ona Sabo-line.
Gege
bi okunrin to lo foro naa to ile ise olopaa leti se salaye , o ni igba ti oun
kirun tan ni iroyin kan oun wi pe, won ti gun omokunrin kan lobe pa ni agbegbe
Opomalu kan naa.
“Iwadii
ti a se leyin ti iroyin naa kan wa fi ye wa wi pe, lojo kinni osu kejila odun
2015, Afolabi Fasasi lo ra ogun oyinbo lowo Dauda Lateefat, eleyii to ko lati
sanwo. Lateefat, leri wi pe oun yoo ko o logbon ti o ba sanwo oun. Leyin eyi ni
won gun omo naa lobe pa ti won si lo ju oku re danu si Isale Opomalu,” asoju ileese
olopaa se lala ye bee fun onidajo.
Sugbon
sa, onidajo O.M. Adeniyi ti n joko ni ile ejo Majisireeti tilu Ilorin salaye wi
pe, yoo dara ti awon olopaa ba tun le fi aye sile fun iwadii to jinle sii lati
mo wulewule oro naa. Ju gbogbo re, Onidajo Adeniyi ni ki won lo fi awon
odaran-afura-si naa si ogba ewon ti ijoba apapo to wa ni Oke-kura ni ilu Ilorin
nigba ti igbejo esun naa yoo tun ma dide laipe.
0 comments:
Post a Comment