*“Wọn ko pe mi sibi ibura gomina tuntun "-
Faleke
*Faleke fi aidunnu rẹ han si alaga APC apapọ
Yahaya Bello |
Ipinlẹ Kogi tun fi itan
tuntun mii balẹ lẹyin ti wọn yan gomina tuntun sipo lỌjọru ọsẹ to koja yii
(27/01/16) lai si igbakeji gomina. Ọgbẹni James Abiodun Faleke ti ẹgbẹ ni ko
gba ipo igbakeji gomina tuntun naa, Yahaya Bello, lo ti ko jalẹ saaju akoko
yii. Ṣugbọn ṣa, Ọgbẹni Faleke ti fi aidunnu rẹ han si alaga egbe ọselu APC
lapapọ, Oloye John Oyegun, gẹgẹ bo ṣe pẹlu awọn to lodi si ifẹ awọn ara ilu
nipa itako Faleke gẹgẹ bi ẹni to yẹ ko jẹ gomina.
"Niwaju Ọlọrun ati eeyan, mo fi n dayin loju wi pe ẹnikẹni ko ti lẹ ronu kan mi lati pe mi sibi eto ibura naa. Mi o gba iwe ipe kankan lọwọ awọn adari ẹgbẹ nipa ayẹyẹ ibura to wa ye naa. Pẹlu bi nnkan ṣe n foju han yii, ohun to daju ni wi pe, ile ẹjọ ni yoo pada da ẹjọ naa gẹgẹ bo ti yẹ," Faleke fi kun alaye rẹ bẹẹ.
Ninu ọrọ apilẹsọ akọkọ
Yahaya Bello gẹgẹ bi gomina, ibẹ lo ti rọ awon eniyan tinu un bi lati fi ọwọ wọnu
ki akurẹtẹ ma ba deba iṣejọba awaarawa ati ẹgbẹ onigbalẹ to ti di aniyikaye.
Nikete ti wọn bura fun
Gomina Yahaya Bello lo ti bẹrẹ si ni yan awọn amugbalẹgbẹ rẹ ti wọn yoo jọ maa ṣiṣẹ
pọ ninu iṣejọba rẹ tuntun.
Gẹgẹ bi iwadii OLAYEMI ONIROYIN, titipa gbọn-ingbọn-in ni ilẹkun ọfiisi igbakeji gomina ṣi wa bi ẹnu bode
ẹwọn. Ẹnikẹni ko si le sọ pato ohun ti yoo pada sẹlẹ saga Faleke to sofo nile
ijọba ipinle naa to kalẹ si Lọkọja.
0 comments:
Post a Comment